Ìyàwó ilé tó di ògbóǹtarìgì nínú ìdíje àgbáyé fáwọn èèyàn tó sán eegun

- Author, Mahjooba Nowrouzi
- Role, BBC News Afghan
Lati ọmọ kekere ni Roya Karimi ti lọ ile ọkọ ti o si bimọ nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun lorilẹede Afghanistan.
Amọ, o ti di ilumọọka bayii ninu idije awọn aṣan-angun nilẹ Yuroopu.
Igbe aye Roya n sọ nipa obinrin ti aṣa da lọwọ kọ amọ ti o ti dominira, to si jẹ awokọṣe fawọn obinrin ẹgbẹ rẹ.
Ọdun mẹrinla sẹyin ni Roya sa kuro ni Afghanistan pẹlu ọmọkunrin rẹ kekere ati iya rẹ, ti wọn si morile orilẹede Norway lati lọ ṣatipo nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe o ti di ominira ni Norway, Roya maa n ro nipa awọn obinrin ti ijọba n fi ẹtọ wọn dun wọn ni orilẹede abinibi rẹ, Aghanistan papaa julọ lati ọdun 2021 tawọn Taliban ti gbajọba pada.
''Mo maa n ranti nigba kugba ti mo ba lọ gbọngan idaraya wi pe mi o ni ominira lati ṣe awọn nnkan ti mo n ṣe bayii nigba ti mo wa ni Afghanistan.
Inu mi dun wi pe mi o si labẹ iru ide bẹẹ mọ, ṣugbọn ọpọ obinrin ni wọn ko le maa n janfaani ẹtọ ọmọniyan bii lilọ ile ẹkọ, o jẹ ohun to bani lọkan jẹ,'' Roya lo sọ bẹẹ.
Ijọba Taliban ti fofin de awọn ọmọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ba tii ju ọdun mejila lọ wi pe wọn o gbọdọ lọ si ile ẹkọ mọ lorilẹede Afghanistan.

Ifarada
''Lonii, awọn ọmọbinrin ni Afghanistan ko lanfaani lati lọ ile ẹkọ mọ.
Koda, wọn o le jade nile lai jẹ pe ọkunrin tẹle wọn jade, bakan naa ni awọn obinrin ko le da gbe igbesẹ kankan funra wọn,'' Roya kọminu.
Roya loun si n reti ọjọ kan tawọn obinrin ni Afghanistan ko ni gbe ninu ibẹru mọ.
Oniruuru ofin ni ijọba Taliban ti fi de awọn obinrin lẹyin ti wọn gbajọba lọdun 2021, nigba tawọn ọmogun Amẹrika fi orilẹede naa silẹ.

Irinajo si Norway
Roya ni igbe aye toun n gbe ni Afghanistan ko tẹ oun lọrun ṣaaju kawọn Taliban to gbajọba gan an.
O nira fun ọpọ obinrin lati gbe iru igbesẹ ti Roya gbe lẹyin to fi ọkọ rẹ silẹ ti o si sa kuro ni Afghanistan.

Roya ni lati bẹrẹ igbe aye ọtun nigba to de si Norway - o ni lati mọ nipa aṣa awọn eeyan orilẹede naa ki o si tun gbọ ede wọn.
Bakan naa, Roya nilo lati wa iṣẹ ti yoo maa ṣe lati tọju ẹbi rẹ.
Roya kọ iṣẹ nọọsi, o si ri iṣẹ nile iwosan kan niluu Oslo ti i ṣe olu ilu orilẹede Norway.
Ẹkọ lati di aṣan-angun

Ibẹrẹ ọtun ni kikọ nipa siṣan eegun jẹ ninu aye Roya, o ni iṣẹ naa ti foun lanfaani lati dominira ninu igbekun toun wa ninu rẹ fun ọpọlọpọ ọdun ni Afghanistan.
Yatọ si iṣẹ nọọsi to n ṣe, Roya tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ, koda, o kẹkọọ gboye lori siṣe ere idaraya.
Ni bayii, Roya ati ọkọ rẹ keji to fẹ ti di ilumọọka tọkọ taya lati Afghanistan ni Norway.
Lọdun to kọja ni Roya fi iṣẹ nọọsi silẹ to si tẹra mọ iṣẹ aṣan-angun, igbesẹ yii si mu ayipada nla ba aye rẹ.

Ọna si awọn idije agbaye

Royan n gbaradi bayii fun idije agbaye awọn elere idaraya aṣan-angun agbaye eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla to n bọ.
Ṣaaju ni Roya gbami ẹyẹ goolu nibi idije ti wọn pe orukọ rẹ ni Stoperiet Open.
Pata alawọ ewe ni Roya wọ to fi kopa ninu idije ọhun.
Lara awọn amuyẹ ti wọn maa n wo ninu idije ere idaraya aṣan-angun ni aṣọ wiwọ, bi awọn oludije ba ṣe dun un wo si ati iru irun ti wọn ṣe sori.
Roya tun fakọyọ lẹyin to gbami ẹyẹ goolu ninu idije Norway Classic 2025.
Idije yii jẹ ọkan lara awọn idije ere idaraya awọn aṣan-angun tawọn eeyan lati oniruuru orilẹede lapa ariwa ilẹ Yuroopu maa n kopa ninu rẹ.
Bi o ṣe fakọyọ nibi idije yii lo jẹ pagede fun idije ilẹ Yuroopu, European Championships eyi to ti sọ ọ di ilumọọka bayii.
Ọkọ Roya ṣe atilẹyin fun un

Ni orilẹede Norway ni Roya ti ba ọkọ rẹ keji, Kamal Jalaluddin, pade ẹni toun naa wa lati orilẹede Afgahanistan.
Iṣẹ ere idaraya aṣan-angun ni Kamal naa yan laayo, o si tun wa lara awọn ololufẹ Roya.
Roya mọ riri atilẹyin ti Kamal n ṣe fun un ni gbogbo igba.
''Atilẹyin Kamal lo fun mi ni igboya lati maa ṣe nnkan nla nla ni ere idaraya aṣan-angun,'' Roya lo sọ bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Roya n ṣe daadaa ni Norwaym ẹbi rẹ ni Afghanistan ko ṣatilẹyin fun un.
Amọ, Roya ni ipakọ o gbọ suti ori ẹlẹgan lo daru lọrọ naa jẹ foun.
Ni ọpọ igba ni wọn n dunkoko mọ ọn lati huwa ipa si i ati lati pa a.
Roya ni gbogbo awọn to n dunkoko mọ oun ko tu irun kankan lara oun.