Bí ìgbẹ́jọ́ Abdulrahman, afurasí tó pa Hafsot Lawal, ṣe lọ ní Ilorin lónìí

Igbẹjọ Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mi ti wọn fẹsun ipaniyan ati ifipabanilopo kan tẹsiwaju loni ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ kwara ni ilu Ilọrin.
Igbẹjọ naa n waye labẹ adajọ Christiana Ajayi.
Ọsẹ to kọja ni ile-ẹjọ da awọn afurasi naa pada si ihamọ ọgba ẹwọn Okekura ni ilu Ilọrin.
Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ lonii?

Nibi igbẹjọ naa to waye ni nnkan bi aago mẹsan an owurọ ni ẹlẹri akọkọ, Dokita Olaleke Olaleye lati ẹka to n sayewo oku ni ile iwosan UITH Ilọrin ti jẹri pe awọn ri iwe gba lọjọ kẹsan, oṣu Kẹrin ọdun 2025 lati yẹ ẹya ara oloogbe wo.
"Lẹyin ayẹwo naa, Insepctor Muhammad gba esi ayewo naa."
Lẹyin ti ile ẹjọ bii lere pe ti o ba ri awọn ẹya ara to sayewo rẹ ṣe o da wọn mọ, Oseni ni bẹẹni.
Wọn si fi abajade ayẹwo naa le e lọwọ lati jẹ ri si, eyi ti adajọ gba wọle gẹgẹ bi ẹri.
Agbẹjọro olujẹjọ kinni tako akọsilẹ esi ayewo naa, sugbon adajọ ko gba ọrọ rẹ wọle.
Olujeri sọ pe ọwọ meji ati awọn ẹya ara to ku ni wọn se ayẹwo rẹ.
Awọn agbẹjọro olujẹjọ gba iwe ayẹwo naa, pe awọn yoo lọ fun akọsẹmosẹ lati ṣalaye rẹ daadaa fun awọn.
Ẹlẹrii keji lati ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣalaye fun ile-ẹjọ pe lọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2025 ni ọkunrin kan ti wọn pe ni Adefalu Lawal wa fi to awọn leti lagọ ọlọpaa ọja ọba niluu Ilọrin pe, oun n wa ọmọ oun Hasfot Lawal to jade ti kosi wọle pada mọ.
O fikun pe, awọn si tọpaṣẹ ẹrọ ibanisọrọ Hasfot de ọdọ Abdurahman nitori oun lo pe e gbẹyin lọjọ naa.
Lọjọ kẹrinla oṣu keji lọwọ tẹ ọkunrin kan ti wọn pe ni Abdurahman Bello lagbegbe isalẹ koto ni ilu Ilọrin.
Abdurahman Bello mu awọn ọlọpaa lọ ile rẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu Keji.
O fikun pe oju ọna Ọffa Garage lawọn de ti Abdurahman Bello fi jẹwo fun awọn pe oun ti sekupa Hasfot Yetunde Lawal ṣugbọn ki ma se sọ fun ẹnikẹni, ti oun si ṣetan lati fun awọn ọlọpaa lowo riba.
O si tun jẹwo fun ọga olopaa DPO. Lẹyin naa ni wọn lọ si ile rẹ nibi ti wọn ri bata Yetunde ati ẹrọ ibanisọrọ meji.
"Nigba ti a wọ yara la ri ada to ni ẹjẹ lara, ọbẹ, rọba ti o rọ ẹjẹ si, ati ike ọda nibi ti ọwọ mejeji ti wọn da ogogoro si wa. O si jẹwọ pe oun pa a lati fi ṣe ogun owo ni."
Ọlọpaa ni Abdurahman yii kan naa lo mu awọn lọ agbegbe Oko-Olowo ni ibi ti o ju ẹya ara to ku si.

Ile-ẹjọ bi ọlọpaa naa lere pe, ṣe to ba ri ẹya ara naa ṣe o da a mọ, o si ni bẹẹni, wọn ṣi ẹya ara naa fun lati wo.
Wọn si ṣafihan fọnran fidio ti awọn ọlọpaa gba silẹ lasiko ti wọn lọ ṣayẹwo ile rẹ.
Ile-ẹjọ gba ọrọ rẹ wolẹ gẹgẹ bi ẹri.
Ẹlẹrii kẹta lati ẹka ajọ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ DSS ipinlẹ kwara tun jẹri tako Abdurahman Bello.
O ṣalaye si waju si pe, Abdurahman sọ fun awọn pe lẹyin ti oun pa Hafsot Yetunde Lawal tan oun ju oku rẹ to ku si ile ilẹ.
Igba ti awọn yoo fi de bẹ, awọn oṣiṣẹ eleto ayika ijọba ipinlẹ kwara ti palẹ awọn idọti mọ.
Awọn si lọ ibi ti wọn n da ilẹ jọ si, ni ibi ti awọn to n salẹ ti ran awọn lọwọ lati ri ẹya ara to ku .
Nigba ti awọn pada fi ọrọ wa Abdurahman Bello lẹnu wo, lo jẹwo pe awọn ẹya ara Hasfot yetunde Lawal ni eyi tawọn ri.
Adajọ gba ọrọ rẹ wole gẹgẹ bi ẹri.
Lẹyin eyi adajọ sun igbẹjọ Siwaju di ọjọ kọkanlelogun osu yi.