"Ìgbeyàwó mi dàrú, ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àti ẹbí kọ̀ mí torí mò ń ṣiṣẹ́ àgbókùújó"

Àkọlé fídíò, "Ìgbeyàwó mi dàrú, ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àti ẹbí kọ̀ mí torí mò ń ṣiṣẹ́ àgbókùújó - Biola Aderin
"Ìgbeyàwó mi dàrú, ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àti ẹbí kọ̀ mí torí mò ń ṣiṣẹ́ àgbókùújó"

Ìgbeyàwó mi dàrú, ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àti ẹbí kọ̀ mí torí mò ń ṣiṣẹ́ àgbókùújó - Biola Aderin

Oniruuru ọna ni awn eeyan fi maa n se ẹyẹ ikẹyin fawọn ololufẹ wọn to ba jade laye.

Lara iru ọna bẹẹ ni gbigbe posi oku jo titi ti yoo fi wọ saare lọ.

Awọn ọkunrin nikan la mọ mọ isẹ agbokujo amọ iyalẹnu lo jẹ fun BBC Yoruba lati ri obinrin kan toun naa n sisẹ agbokujo.

Obinrin naa, Biola Olorunyomi Aderin lo jẹ abo to n sisẹ ti a mọ mọ awọn akọ.

Idi ree ti BBC Yoruba se kan si obinrin naa nilu Akure lati mọ ohun to gbe de idi isẹ naa, ipenija to n koju ati iwoye to ni fun ọjọ ọla.

Biola Aderin n gbe oku jo pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ

"Ọkọ mi ni ki n mu laarin oun ati isẹ, ti mo si mu isẹ, bi igbeyawo se pari niyẹn"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Biola Aderin salaye pe ọdun 2005 ni oun bẹrẹ isẹ agbokujọ.

O ni ẹgbẹrun meji abọ Naira (N2,500) ni oun n gba lori isẹ agbokujo kan ti oun ba se, ọjọ meji si jẹ ẹgbẹrun marun naira.

Biola, tii se ọmọ orukan ni oun, ti ko si iya tabi baba mọ, ti atijẹ, atimu si di ọran nla fun oun.

O fikun pe nigba ti oun se igbeyawo tan, oun ba ọkọ oun jiroro lati pada sidi isẹ agbokujo naa.

"Ọrọ naa ko ba ọkọ mi lara mu, to si ni ki n mu ọkan ninu oun tabi isẹ agbokujo.

Ọmọ meji ni mo ti bi fun, ti mo si pinnu lati fara mọ isẹ agbokujo eyi to fopin si igbeyawo wa.

Idi ree ti mo se kuro nilu Eko ti mo n gbe tẹlẹ pẹlu ọkọ mi, ti mo si pada silu Akure nibi ti mo ti n sisẹ agbokujo.

Biola Aderin n gbe oku jo pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ

"Ẹbi ati ara kọ mi tori pe mo n se isẹ agbokujo, wọn ni isẹ ti ko se mu yangan fun ọmọluabi ni"

Nigba to n salaye ọpọ oun ti oju rẹ ri nidi isẹ agbokujo, Biola Aderin sọrọ, ilẹ kun.

Biola Aderin tẹsiwaju pe isẹ naa n mu ki inu oun maa dun, ti oun ko si se isẹ asẹwo.

"Awọn ọrẹ ati ẹbi lo kọ mi silẹ nigba ti mo bẹrẹ isẹ naa, ti wọn ko si fẹ fara mọ isẹ naa.

Ọpọ wọn si ni ko fẹ fun mi lowo tabi ran mi lọwọ, ti wọn si tun korira isẹ ti mo se.

Wọn ro pe isẹ t imo n se ko se mu yangan gẹgẹ bi isẹ ọmọluabi.

Amọ n ko tọrọ owo lọwọ ẹnikẹni wọn amọ loni bayii, wọn t iyi pada, ti wọn si ti n pada wa mi.

Koda, bi oku ba ku, emi ni wọn maa n fẹ ki n se e akoso bi wn yoo ti se ẹyẹ ikẹyin fun oku naa."

Biola Aderin n gbe oku jo pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ

"Awọn ọkunrin ti a dijọ n sisẹ gbe oku jo dubulẹ, ti wọn ko si le dide mọ, araalu kan lo lọ gbe mama kan dide lori aga, ki awọn ọkunrin akẹẹgbẹ naa to le dide nibi ti wọn sun si"

Biola Aderin wa mẹnuba ọjọ manigbagbe to ri lẹnu isẹ agbokujo eyi to ka ni laya pupọ.

O ni ọjọ ti oun ko le gbagbe nidi isẹ naa ni ọjọ kan ti awọn gbe oku lọ silu kan ni Akoko, ti awọn ọkunrin ti wọn dijọ lọ sisẹ, ti wọn n gbe oku jo dubulẹ, ko si le dide duro mọ fun igba pipẹ.

"Awọn Ọkunrin naa sa dubulẹ, lai le dide mọ, se ni idi wọn lẹ mọ ilẹ ti a ko si mọ oun ti a fẹ se mọ.

Araalu naa kan lo lọ fa iya kan to joko sori aga dide pe ko dide naro, se o fẹ pa awọn ọmọ ọlọmọ ni.

Bi mama naa se dide duro, ni awọn akẹẹgbẹ mi naa lee dide duro nibi ti wọn dubulẹ si.

A ko le tẹsiwaju lati maa se ẹyẹ fun oku naa mọ, a kan wọ sib ikan ni, ti a si kuro nibẹ."

Biola Aderin ni oun kan fẹ sisẹ agbokujo fun igba diẹ ni, ki oun le tu owo jọ lati si sọọbu, ki oun si maa ta ọja oun.